Èso: Fruits
Across
- 2. Eléyìí máa ń so yí ọrùn igi rẹ̀ ká. Tí wọ́n bá pa á tán, omi máa ń wà nínú rẹ̀. Wọ́n máa ń fọ mọ́ òkúta líle kí wọn tó lè rí èso yìí jẹ
- 4. Eléyìí rí róbótó. Tí wọ́n bá pá tán, awẹ́ méjì ló máa ń ní. Èso yìí funfun. Ó dùn, ṣùgbọ́n tí ènìyàn bá mumi lẹ́yìn tó bá jẹ́ tán, ó máa ń korò
- 9. Ilẹ̀ ni eléyìí ti máa ń so. Ìtàkùn sì ni 'igi' rẹ̀. Tí wọ́n bá làá tán, ó máa ń ní èso tí ó dàbí ẹ̀gúsí
- 11. Orí igi ni eléyìí máa ń so sí. Tí kò bá tíì pọ́n, á ní àwọ̀ ewéko, tó bá pọ́n ó lè ní àwọ̀ yẹ́lò. Wọ́n lè fi igi rẹ̀ dáná tí ó bá gbẹ tán
- 13. Ẹyọ kan ni eléyìí sáábà máa ń so. Ó lè tóbi tó orí ọmọdé, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ díẹ̀. Ó máa ń ní ẹ̀gún lára. Wọ́n ní láti bẹ èèpo rẹ̀ tí ó dàbí ara ọ̀ọ̀nì kí ó tó lè ṣeé jẹ
- 14. Kóró èso yìí ni wọ́n ń pè ní àpọ̀n. Ó dùn, ṣùgbọ́n ó fẹ́ korò díẹ̀. Wọn máa ń fi kóró rẹ̀ se ọbẹ̀
Down
- 1. Èso yìí máa ń ní kóró kan péré, kóró rẹ̀ kìí dúró sínú èso yìí, ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni ó máa ń lẹ̀ mọ́. Orúkọ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àyálò ọ̀rọ̀
- 3. Èso yìí kò ṣeé jẹ láì jẹ́ pé ó pọ́n. Ọ̀bọ fẹ́ràn rẹ̀ púpọ̀. Igi rẹ̀ kò wúlò fún nǹkan kan.
- 5. Tí a bá pa èso yìí, oje funfun ló máa ń kọ́kọ́ jáde. Ó dùn, ó kan díẹ̀. Kóró rẹ̀ rí pẹlẹbẹ
- 6. Fruits
- 7. Eléyìí máa ń so yí ọrùn igi rẹ̀ ká ni. Kò ṣeé jẹ láì jẹ́ pé ó pọ́n. Kóró rẹ̀ dúdú. Igi rẹ̀ kò wúlò fún nǹkan kan
- 8. Àwọn kan kò gbà pé èso ni eléyìí torí ọbẹ̀ ni wọ́n sáábà máa ń lòó fún. Orúkọ òun náà wà nínú àwọn àyálò ọ̀rọ̀
- 10. Eléyìí fi ara jọ ọparun, ṣùgbọ́n ó tínrín ju ọparun. Ibi odò ni wọ́n sáábà máa ń gbìn ín sí. Oje rẹ̀ dùn bíi ṣúgà
- 12. Kóró kan pẹlẹbẹ ni ó máa ń ní. Orúkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú 'M'. Orúkọ yìí jẹ́ ọ̀kan lára àyálò ọ̀rọ̀